- Wọn o ṣe imọra kuro nibi ẹgbin kekere ati nla ni majẹmu fun iranti Ọlọhun ti ọla Rẹ ga.
- Anabi – ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a – maa n dunni mọ́ iranti Ọlọhun ti ọla Rẹ ga.
- Ṣiṣenilojukokoro lori iranti Ọlọhun ti ọla Rẹ ga ni ọpọlọpọ ni gbogbo igba lati fi kọṣe Anabi – ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a -, ayaafi ni awọn ìṣesí ti wọn kọ ṣiṣe iranti nibẹ, gẹgẹ bíi asiko gbigbọ bukaata (itọ tabi igbẹ).