- Ṣiṣenilojukokoro lori pipọ ni kika Alukurāni.
- O n bẹ fun oluka nibi gbogbo harafi kọọkan ninu gbolohun ti o ba n ka ẹsan kan ti wọn o ṣe adipele rẹ ni ọna mẹwaa iru rẹ.
- Gbígbòòrò ikẹ Ọlọhun ati ọrẹ Rẹ latari pe O ṣe adipele ẹsan fun àwọn ẹrú Rẹ ni ti ọla ati ọrẹ lati ọdọ Rẹ.
- Ọla ti n bẹ fun Alukurāni lori ọrọ ti o yatọ si i, ati jijọsin pẹlu kika a, ìyẹn ri bẹẹ nitori pe ọrọ Ọlọhun ti O ga ni.