“Gbólóhùn meji kan ti wọn fúyẹ́ lori ahọ́n, ti wọn wúwo ninu òṣùwọ̀n, ti Ajọkẹ-aye nífẹ̀ẹ́ si méjèèjì
Lati ọdọ Abu Hurairah, ki Ọlọhun yọnu si i, o gba a wa lati ọdọ Anabi, ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a, o sọ pe: “Gbólóhùn meji kan ti wọn fúyẹ́ lori ahọ́n, ti wọn wúwo ninu òṣùwọ̀n, ti Ajọkẹ-aye nífẹ̀ẹ́ si méjèèjì ni: SUBHAANALLOOHIL AZEEM, SUBHAANALLOOHI WA BIHAMDIHII”.
Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí ni
Àlàyé
Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ nipa gbólóhùn méjì kan ti ọmọniyan maa n pe ni gbogbo iṣesi láìsí inira nibẹ, ẹ̀san méjèèjì si tobi ninu òṣùwọ̀n, ati pe Oluwa wa Ajọkẹ-aye ti ọla Rẹ ga si nífẹ̀ẹ́ si méjèèjì:
SUBHAANALLOOHIL AZEEM, SUBHAANALLOOHI WA BIHAMDIHII; fun nǹkan ti méjèèjì ko sinu bii iroyin Ọlọhun pẹlu titobi ati pípé, ati fifọ Ọ mọ kuro nibi àléébù.
Hadeeth benefits
Iranti ti o tobi ju ni ki èèyàn da afọmọ Ọlọhun papọ mọ ẹyìn rẹ.
Alaye gbígbòòrò aanu Ọlọhun fun awọn ẹru Rẹ, O maa n ṣẹsan iṣẹ kekere pẹlu ẹ̀san ti o pọ.
Share
Use the QR code to easily share the message of Islam with others