Ọ̀rọ̀ ti Ọlọhun nífẹ̀ẹ́ si julọ mẹrin ni: SUBHAANALLAH, ati ALHAMDULILLAAH, ati LAA ILAAHA ILLALLOOH, ati ALLAHU AKBAR, èyíkéyìí ti o ba wù ọ ni o le fi bẹ̀rẹ̀ nínú wọn”
Láti ọ̀dọ̀ Samurah ọmọ Jundub- ki Ọlọhun yọnu si i- o sọ pé: Ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pé: Ọ̀rọ̀ ti Ọlọhun nífẹ̀ẹ́ si julọ mẹrin ni: SUBHAANALLAH, ati ALHAMDULILLAAH, ati LAA ILAAHA ILLALLOOH, ati ALLAHU AKBAR, èyíkéyìí ti o ba wù ọ ni o le fi bẹ̀rẹ̀ nínú wọn”.
Muslim gba a wa
Àlàyé
Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n ṣàlàyé pe ọ̀rọ̀ ti Ọlọhun nífẹ̀ẹ́ si julọ mẹ́rin ni:
SUBHAANALLAH: O n túmọ̀ sí fifọ Ọlọhun mọ́ kuro nibi gbogbo adinku.
ALHAMDULILLAAH: Oun ni fífi pípé ròyìn Ọlọhun pẹlu ìfẹ́ Rẹ̀ ati gbigbe E tobi.
LAA ILAAHA ILLALLOOH: Ìtumọ̀ rẹ ni: Ko si ẹni ti a le maa jọ́sìn fun ni ododo ayafi Ọlọhun.
ALLAHU AKBAR: Ìtumọ̀ rẹ ni: O gbọnngbọn, O si tobi, O si ni agbara ju gbogbo nnkan lọ.
Ati pe ọla rẹ ati rírí ẹsan rẹ, ko beere fun títò ó tẹle ara wọn ti a ba n pe wọn jáde lẹ́nu.
Hadeeth benefits
Irọrun sharia, latara pe o le bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú èyíkéyìí tí o ba fẹ ninu awọn gbolohun naa.
Share
Use the QR code to easily share the message of Islam with others