Lati ọdọ Abu Mūsa - ki Ọlọhun yọnu si i - lati ọdọ Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - o sọ pe: «Dajudaju Ọlọhun ti O biyi ti O gbọnngbọn maa n t...
Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - n funni ni iro pe: Dajudaju Ọlọhun ti ọla Rẹ ga maa n gba tituuba awọn ẹru rẹ, ti ẹru ba da ẹṣẹ kan ni ọsan t...
Lati ọdọ Abu Hurayra – ki Ọlọhun yọnu si i– dajudaju Ojiṣẹ Ọlọhun – ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a – sọ pe: «Oluwa wa ti ọla Rẹ ga maa n sọkalẹ ni gbo...
Anabi – ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - ṣe alaye pe dajudaju Ọlọhun ti ọla Rẹ ga maa n sọkalẹ ni gbogbo oru si sanmọ aye nigba ti o ba ku idamẹta igb...
Láti ọ̀dọ̀ An-Nuhmaan ọmọ Basheer- ki Ọlọhun yọnu si i- o sọ pé: Mo gbọ lẹ́nu ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ti o n sọ pe- An-Nuhmaa...
Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n ṣàlàyé òfin kan ti o kárí nibi awọn nǹkan, o si pin si mẹta ninu ṣẹria: Ẹ̀tọ́ ti o fi ojú hàn, ati eewọ ti...
Lati ọdọ Ibnu Abbas- ki Ọlọhun yọnu si awọn mejeeji- o sọ pe: “Mo wa lẹyin Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ni ọjọ kan, o wa sọ pe: “Irẹ ọmọk...
Ibnu Abbaas- ki Ọlọhun yọnu si i- n sọ pé oun kéré nígbà tí oun n gun nǹkan ọ̀gùn pẹ̀lú Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a-, o wa sọ pé: Mo maa...
Lati ọdọ Sufyan ọmọ Abdullahi Ath-Thaqoofiy- ki Ọlọhun yọnu si i- o sọ pe: Mo sọ pé: Irẹ ojiṣẹ Ọlọhun, sọ ọrọ kan fun mi ninu Isilaamu ti mi ko nii bi...
Saabe Sufyan ọmọ Abdullahi- ki Ọlọhun yọnu si i- bi Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- leere lati kọ oun ni ọrọ kan ti o ko awọn ìtumọ̀ Isilaam...
Lati ọdọ Abu Mūsa - ki Ọlọhun yọnu si i - lati ọdọ Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - o sọ pe: «Dajudaju Ọlọhun ti O biyi ti O gbọnngbọn maa n tẹ ọwọ Rẹ ni oru lati gba tuuba ẹni ti o ba da ẹṣẹ ni ọsan, O si tun maa n tẹ ọwọ Rẹ ni ọsan lati gba tuuba ẹni ti o da ẹṣẹ ni oru titi oorun o fi yọ ni ibi ti o ti maa n wọ».
Lati ọdọ Abu Hurayra – ki Ọlọhun yọnu si i– dajudaju Ojiṣẹ Ọlọhun – ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a – sọ pe: «Oluwa wa ti ọla Rẹ ga maa n sọkalẹ ni gbogbo oru si sanmọ aye nigba ti o ba ṣẹku idamẹta igbẹyin, yio wa maa sọ pe: «Tani yio pe Mi ki n maa da a lohun? Tani yio bi Mi leere ki n si maa fun un? Tani yio wa aforijin Mi ki n si ṣe aforijin fun un?».
Láti ọ̀dọ̀ An-Nuhmaan ọmọ Basheer- ki Ọlọhun yọnu si i- o sọ pé: Mo gbọ lẹ́nu ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ti o n sọ pe- An-Nuhmaan wa na ìka rẹ méjèèjì si etí rẹ méjèèjì-: “Dajudaju nǹkan ẹtọ fi ojú hàn, dájúdájú nǹkan eewọ naa fi ojú hàn, o wa n bẹ láàrin àwọn méjèèjì àwọn nǹkan ti wọn ruju, ti ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn èèyàn ko si mọ wọn, ẹni tí ó bá ṣọra fun awọn iruju naa, o ti wa mímọ́ fun ẹsin rẹ ati ọmọlúwàbí rẹ, ẹni tí o ba ko sinu àwọn ìríjú naa, yoo ko sinu nǹkan eewọ, o da gẹgẹ bii adaranjẹ̀ ti n da ẹran jẹ̀ ni etí ilẹ̀ ti wọn dá ààbò bò, o sunmọ ki o da ẹran wọ inu rẹ. Ẹ tẹti ẹ gbọ, dájúdájú gbogbo ọba ni o ni ilẹ̀ ti wọn dá ààbò bò. Ẹ tẹti ẹ gbọ, ilẹ Ọlọhun ti a da ààbò bò ni àwọn nǹkan ti O ṣe ni eewọ, ẹ tẹti ẹ gbọ, dájúdájú baaṣi ẹran kan n bẹ nínú ara, ti o ba ti dáa, gbogbo ara ti dáa, ti o ba si ti bajẹ, gbogbo ara ti bajẹ, ẹ tẹti ẹ gbọ, oun naa ni ọkàn”.
Lati ọdọ Ibnu Abbas- ki Ọlọhun yọnu si awọn mejeeji- o sọ pe: “Mo wa lẹyin Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ni ọjọ kan, o wa sọ pe: “Irẹ ọmọkunrin yii, emi yoo kọ ọ ni àwọn ọrọ kan pe: Máa ṣọ́ Ọlọhun, yoo si daabo bo ọ. Maa ṣọ Ọlọhun, iwọ yoo ri I ni iwaju rẹ. Ti o ba beere, beere lọwọ Ọlọhun, ati pe nígbà tí o ba wa iranlọwọ, wa iranlọwọ Ọlọhun. Mọ pe ti gbogbo ẹda ba pejọ lati ṣe nkan lati ṣe anfaani fun ọ, wọn ko nii ṣe àǹfààní kankan fun ọ rara ayafi pẹ̀lú nǹkan ti Ọlọhun ti kọ fun ọ. Ati pe ti wọn ba pejọ lati ṣe nkan lati ṣe ipalara fun ọ, wọn ko nii ṣe ipalara fun ọ rara ayafi pẹ̀lú nǹkan ti Allah ti kọ fun ọ. Wọn ti gbé àwọn ìkọ̀wé sókè, àwọn tákàdá si ti gbẹ.”
Lati ọdọ Sufyan ọmọ Abdullahi Ath-Thaqoofiy- ki Ọlọhun yọnu si i- o sọ pe: Mo sọ pé: Irẹ ojiṣẹ Ọlọhun, sọ ọrọ kan fun mi ninu Isilaamu ti mi ko nii bi ẹnikẹni leere nípa rẹ yàtọ̀ si ẹ, o sọ pe: "Sọ pe: Mo gbagbọ ninu Ọlọhun, lẹyin naa ki o duro deedee".
Lati ọdọ An-Nu‘mān ọmọ Bashīr - ki Ọlọhun yọnu si i - o sọ pe: Ojiṣẹ Ọlọhun - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - sọ pe: «Apejuwe awọn Mumuni nibi nini ifẹ ara wọn ati kikẹ ara wọn ati nini aanu ara wọn da gẹgẹ bi apejuwe odidi ara, nigba ti orike kan ba n ke irora gbogbo ara yoku ni yio para pọ pẹlu rẹ nibi aisun ati igbona.
Lati ọdọ Uthman ọmọ Affan- ki Ọlọhun yọnu si i- o sọ pe: Ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pe: “Ẹni ti o ba ṣe aluwala ti o si ṣe aluwala naa daadaa, awọn àṣìṣe rẹ maa jade kúrò lára rẹ titi yoo fi maa jade lati abẹ awọn èékánná rẹ”.
Lati ọdọ Abu 'Ayyub Al-Ansari- ki Ọlọhun yọnu si i-, dajudaju Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pé: «Ti ẹ ba ti wa si aaye igbọnsẹ yin ẹ ko gbọdọ da oju kọ kibula, ẹ ko si tun gbọdọ da ẹyin kọ ọ, amọ ẹ daju kọ ila oorun tabi iwọ oorun» Abu Ayyūb sọ pe: A wa si Shām ti a si ri awọn ile igbọnsẹ ti wọn ti mọ daju kọ kibula, nitori naa a maa n yẹ si ẹgbẹ, ti a si tun maa n wa aforijin Ọlọhun ti ọla Rẹ ga.
Lati ọdọ Abu Qatāda- ki Ọlọhun yọnu si i - o sọ pe: Ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - sọ pe: «Ẹnikẹni ninu yin o gbọdọ fi ọwọ ọtun rẹ mu nkan ọmọkunrin rẹ nigba ti o ba n tọ, ko si gbọdọ fi ọwọ rẹ ọtun ṣe imọra nibi igbọnsẹ, ko si gbọdọ fẹ atẹgun si inu ife imumi».
Lati ọdọ Abu Hurayra - ki Ọlọhun yọnu si i - lati ọdọ Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - o sọ pe: «Ọlọhun o nii gba irun ẹnikẹni ninu yin ti o ba ti ni ẹgbin lara titi ti yio fi ṣe aluwala».
Lati ọdọ Jaabir - ki Ọlọhun yọnu si i - o sọ pe: Umar ọmọ Khatob fun mi niroo pe: Dajudaju arakunrin kan ṣe aluwala ni o wa fi aaye eekanna silẹ nibi ẹsẹ rẹ, ni Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - wa ri i ti o si sọ pe: «Pada ki o si lọ ṣe aluwala rẹ daadaa» ni o ba pada, lẹyin naa ni o kirun.
Lati ọdọ Abdullah ọmọ Amru ki Ọlọhun yọnu si awọn mejeeji o sọ pe: A ṣẹri pada pẹlu ojiṣẹ Ọlọhun - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - lati Makkah lọ si Madina titi ti a fi kan omi ni oju-ọna, awọn ikọ kan yara fun irun Asri, ti wọn si ṣe aluwala ni ẹni ti n kanju, ni a ba wa ba wọn ti awọn gigisẹ wọn han ti omi o si de ibẹ, ni Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - wa sọ pe: «Egbe ki o maa ba gbogbo gigisẹ (ti omi o de) ninu ina, ẹ ṣe aluwala yin daadaa».