Apejuwe awọn Mumuni nibi nini ifẹ ara wọn ati kikẹ ara wọn ati nini aanu ara wọn da gẹgẹ bi apejuwe odidi ara, nigba ti orike kan ba n ke irora gbogbo ara yoku ni yio para pọ pẹlu rẹ nibi aisun ati igbona
Lati ọdọ An-Nu‘mān ọmọ Bashīr - ki Ọlọhun yọnu si i - o sọ pe: Ojiṣẹ Ọlọhun - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - sọ pe: «Apejuwe awọn Mumuni nibi nini ifẹ ara wọn ati kikẹ ara wọn ati nini aanu ara wọn da gẹgẹ bi apejuwe odidi ara, nigba ti orike kan ba n ke irora gbogbo ara yoku ni yio para pọ pẹlu rẹ nibi aisun ati igbona.
Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí ni
Àlàyé
Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - ṣe alaye pe dajudaju o jẹ dandan ki ìṣesí awọn Musulumi pẹlu ara wọn o maa jẹ nibi nini ifẹ daadaa ati ikẹ ati ikunlọwọ ati aranṣe, ati titara pẹlu nkan ti o ba ṣẹlẹ si wọn ni inira, gẹgẹ bii ara kan soso, nigba ti oríkèé kan ninu rẹ ba ṣe aisan, gbogbo ara ni yio ba a ṣe papọ nibi aisun ati igbona.
Hadeeth benefits
O tọ (o jẹ dandan) gbigbe awọn iwọ awọn Musulumi tobi ati ṣiṣe ojukokoro lori ikun wọn lọwọ ati ki apakan wọn o maa ṣàánú apa miran.
O tọ (o jẹ dandan) ki o maa bẹ laarin awọn olugbagbọ ifẹ ati aranṣe.
Share
Use the QR code to easily share the message of Islam with others