- Wọn o nii gba irun ẹni ti o ni ẹgbin lara titi ti yio fi ṣe imọra pẹlu iwẹ kuro nibi ẹgbin nla ati pẹlu aluwala kuro nibi ẹgbin kekere.
- Aluwala oun ni bibu omi ati yiyi i po ninu ẹnu ati titu u jade, lẹyin naa ni fifi eemi rẹ fa omi si inu imu, lẹyin naa ni fifin in jade, lẹyin naa ni fifọ oju ni ẹẹmẹta, lẹyin naa ni fifọ ọwọ mejeeji de igunpa ni ẹẹmẹta, lẹyin naa ni pipa gbogbo ori ni ẹẹkan, lẹyin naa ni fifọ ẹsẹ mejeeji de koko ẹsẹ ni ẹẹmẹta.