- Ipilẹ ẹsin ni nini igbagbọ ninu Ọlọhun pẹlu ijẹ Oluwa Rẹ ati ijẹ Ọlọhun Rẹ ati awọn orukọ Rẹ ati awọn iroyin Rẹ.
- Pataki iduro ṣinṣin lẹyin igbagbọ, ati itẹsiwaju nibi ijọsin, ati fifi ẹsẹ rinlẹ lori ìyẹn.
- Igbagbọ jẹ majẹmu itẹwọgba awọn iṣẹ.
- Nini igbagbọ ninu Ọlọhun, ko nnkan ti adisọkan rẹ jẹ dandan sinu ninu awọn adisọkan igbagbọ ati awọn ipilẹ rẹ, ati nnkan ti o tẹle ìyẹn ninu awọn iṣẹ ọkan, ati itẹle ati gbigba fun Ọlọhun ni kọkọ ati ni gbangba.
- Iduro ṣinṣin ni ki èèyàn má kúrò ni oju ọna, pẹlu ṣíṣe awọn nnkan ti wọn jẹ dandan ati gbigbe awọn nnkan ti a kọ ju silẹ.