- Gbigba tuuba n tẹ síwájú lopin ìgbà tí ilẹkun rẹ ba si wa ni ṣiṣi silẹ, ati pe wọn maa ti ilẹkun rẹ pẹlu yiyọ oorun ni ibuwọ rẹ, ati pe ki ọmọniyan o tuuba siwaju ipọka iku, oun naa ni ki ẹmi de ọ̀nà ọ̀fun.
- Ki eeyan ma sọ ìrètí nu torí ẹṣẹ, dajudaju amojukuro Ọlọhun ti mimọ n bẹ fun Un ati ikẹ Rẹ nkan ti o gbaaye ni, ati pe ilẹkun tituuba wa ni ṣiṣi silẹ.
- Awọn majẹmu tituuba: Akọkọ: Jijawọ kuro ninu ẹṣẹ, ẹlẹẹkeji: kika abamọ l'ori ṣiṣe é, ẹlẹẹkẹta: Ìpinnu lati ma pada si ibẹ mọ láéláé, eyi ni nibi awọn ẹtọ Ọlọhun ti ọla Rẹ ga, amọ ti o ba wa sokọ mọ ẹtọ awọn ẹru, nigba naa wọn ṣe e ni majẹmu tituuba ki o da ẹtọ yẹn pada si ọdọ ẹni ti o ni i, tabi ki ẹni ti o ni ẹtọ yẹn o yaafi rẹ.