- Jijẹ dandan fifọ ẹsẹ mejeeji nibi aluwala; torí pé dajudaju ti pipa a ba lẹtọọ ni ko nii ṣe adehun ina fun ẹni ti o fi fifọ gigisẹ silẹ.
- Jijẹ dandan fifi omi kari gbogbo awọn oríkèé ara ti a maa n fọ, ati pe ẹnikẹni ti o ba fi aaye kekere kan silẹ ninu nkan ti fifọ rẹ jẹ dandan ni ti imọọmọ ṣe ati ailakasi, irun rẹ ko ni alaafia.
- Pataki kikọ alaimọkan ni ẹkọ ati ṣiṣe amọna rẹ.
- Onimimọ a maa kọ nkan ti o ba ri nibi rira ọranyan ati sunnah lare pẹlu ọna ti o ba wa ni ibamu.
- Muhammad Ishāq Ad-dahlawiy sọ pe: Iran mẹta ni Isbāg: *Ọranyan* oun naa ni mimu omi kari gbogbo aaye naa (oríkèé ara ti a fẹ fọ) ni ẹẹkan, ati *Sunnah* oun naa ni fifọ ni ẹẹmẹta, ati *Eyiti a fẹ* oun naa ni fifa a gun pẹ̀lú fifọ ni ẹẹmẹta.