- Ọgbọn ti o n bẹ nibi ìyẹn ni gbigbe kaaba abiyi tobi ati ṣiṣe aponle rẹ.
- Wíwá aforijin lẹyin jijade kuro ni aaye igbọ bukaata.
- Didara ikọnilẹkọọ Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a -; latari pe nígbà tí o darukọ nkan ti wọn kọ, o tọka si eyi ti o lẹtọọ naa.