- Jijẹ dandan yiyara lati pàṣẹ daadaa, ati titọ alaimọkan ati onigbagbe sọnà, pataki julọ ti bibajẹ ijọsin ba maa jẹ yọ latara aidara yẹn.
- Jijẹ dandan fifi omi kari gbogbo ara, ati pe ẹni ti o ba fi ipin (aaye) kan ninu oríkèé ara silẹ - koda ki o ma to nkankan - aluwala rẹ o ni alaafia o si tun jẹ dandan fun un ki o tun un ṣe tí alaafo yẹn ba ti gun.
- Ṣiṣe imaa ṣe aluwala daadaa ni ofin, ati pe iyẹn ni pipe e ati ṣiṣe e daadaa lori ojupọna ti ofin fi pàṣẹ rẹ.
- Ẹsẹ mejeeji ninu awọn oríkèé aluwala ni wọ́n wa, pipa mejeeji o si lẹẹ tọ, bí kò ṣe pe ko si ibuyẹ kuro nibi fifọ (ẹsẹ mejeeji).
- Yiyara ṣe awọn oríkèé aluwala tẹle ara wọn jẹ nkan to lẹẹ tọ, ni èyí ti o ṣe pe yio fọ oríkèé kọọkan ṣíwájú ki èyí tí o ṣaaju rẹ o to gbẹ.
- Aimọkan ati igbagbe wọn o lee bi ọranyan wo, nkan ti wọn le mu kuro ni ẹṣẹ, nitori naa arakunrin ti ko ṣe aluwala rẹ daadaa latara aimọkan rẹ Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - o bi ọranyan wo fun un, oun naa ni aluwala, o tun pa a l'aṣẹ ki o tun un ṣe ni.