Àlàyé
Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ṣe adehun iya fun ẹni ti o ba ṣe àwọn nǹkan kan ninu ijọ rẹ pẹlu gbólóhùn rẹ pe: “Kii ṣe ara wa”, ninu rẹ naa ni:
Akọkọ: “Ẹni ti o ba retí ìṣẹ̀lẹ̀ aburú láti ara nǹkan tabi ti wọn ba a ṣe e”, ipilẹ rẹ ni: Titu ẹyẹ sílẹ̀ nígbà tí èèyàn ba fẹ bẹ̀rẹ̀ iṣẹ kan bii ìrìn-àjò, tabi òwò, ati bẹẹ bẹẹ lọ, ti o ba fò lọ si apá ọ̀tún, o maa retí ìṣẹ̀lẹ̀ rere, o si maa ṣe nǹkan ti o gbèrò láti ṣe, ti o ba wa fò lọ sí apá òsì, o maa retí aburú, ko si nii ṣe nnkan ti o gbero lati ṣe mọ, ko ni ẹtọ ki èèyàn ṣe èyí fúnra rẹ, tabi ki o ni ki ẹlòmíràn ba oun ṣe e, ìrètí ìṣẹ̀lẹ̀ aburu latara èyíkéyìí nǹkan maa ko sínú ìyẹn, yálà nǹkan ti a n gbọ́ ni tabi nǹkan ti a n rí, bii ẹyẹ, tabi awọn ẹranko, tabi awọn alaabọ ara, tabi nọmba, tabi awọn ọjọ, ati bẹẹ bẹẹ lọ.
Ẹẹkeji: “Ẹni ti o ba pe apemọra imọ kọ̀kọ̀ tabi ti wọn sọ imọ kọ̀kọ̀ fun”, ẹni tí ó bá pe apemọra imọ kọkọ pẹlu lílo ìràwọ̀ ati nǹkan mìíràn, tabi ti o wa si ọdọ ẹni ti n pe apemọra imọ kọ̀kọ̀ bii adágbigba ati ẹni ti o jọ ọ, ti o wa gba ohun ti o n sọ gbọ́ pẹ̀lú pipe apemọra imọ kọ̀kọ̀, o ti ṣe aigbagbọ si nǹkan ti wọn sọ̀kalẹ̀ fun Muhammad (ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a).
Ẹẹkẹta: “Ẹni ti o ba sà sí èèyàn tabi ti wọn ba a sà sí èèyàn”, oun naa ni ẹni tí o ṣe oogun funra rẹ, tabi o ni ki ẹlòmíràn ba oun ṣe e; lati fi ṣe ẹnikan ni anfaani, tabi ko inira bá a, tabi ti o ta kókó kan pẹlu dídi òwú ati oogun le e lori pẹlu kika àwọn gbólóhùn iṣọra ti o jẹ eewọ le e lori, ki o tun wa fẹnu fátẹ́gùn túẹ́túẹ́ sínú rẹ.