/ Fifi ẹyẹ furamọ aburu ati oore ẹbọ ni, fifi ẹyẹ furamọ aburu ati oore ẹbọ ni, fifi ẹyẹ furamọ aburu ati oore ẹbọ ni,- lẹẹmẹta-", ko si ninu wa afi, ṣùgbọ́n Ọlọhun- Alagbara ti O gbọnngbọn- n mu u lọ pẹlu igbarale Ọlọhun...

Fifi ẹyẹ furamọ aburu ati oore ẹbọ ni, fifi ẹyẹ furamọ aburu ati oore ẹbọ ni, fifi ẹyẹ furamọ aburu ati oore ẹbọ ni,- lẹẹmẹta-", ko si ninu wa afi, ṣùgbọ́n Ọlọhun- Alagbara ti O gbọnngbọn- n mu u lọ pẹlu igbarale Ọlọhun...

Lati ọdọ Abdullahi ọmọ Mas'ud- ki Ọlọhun yọnu si i- lati ọdọ ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- o sọ pe: "Fifi ẹyẹ furamọ aburu ati oore ẹbọ ni, fifi ẹyẹ furamọ aburu ati oore ẹbọ ni, fifi ẹyẹ furamọ aburu ati oore ẹbọ ni,- lẹẹmẹta-", ko si ninu wa afi, ṣùgbọ́n Ọlọhun- Alagbara ti O gbọnngbọn- n mu u lọ pẹlu igbarale Ọlọhun.
Abu Daud ati Tirmiziy ati Ibnu Maajah ati Ahmad ni wọ́n gba a wa

Àlàyé

Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ṣe ikilọ kuro nibi fifi ẹyẹ fura mọ aburu, oun ni fifuramọ aburu latara eyikeyii nnkan kan ti a le gbọ́ lo jẹ ni tabi ti a le ri, ninu awọn ẹyẹ tabi awọn ẹranko tabi awọn oni aisan tabi awọn onka tabi awọn ọjọ tabi eyi ti o yàtọ̀ si wọn, Ṣugbọn o dárúkọ awọn ẹyẹ nitori pe o gbajumo nigba aimọkan, ati pe ipilẹ rẹ ni títú awọn ẹyẹ silẹ nigba ti wọn ba fẹ bẹ̀rẹ̀ iṣẹ kan bii irin-ajo tabi okowo tabi eyi ti o yàtọ̀ si ìyẹn, ti o ba fo si apa ọtun, yoo ni ifuramọ daadaa yoo si maa ba nnkan ti o fẹ ṣe lọ, ti o ba fo si apa osi, yoo ni ifuramọ aburu yoo si da ọwọ duro kuro nibi nnkan ti o fẹ ṣe. O sọ pe dajudaju ẹbọ ni, ifuramọ aburu ẹbọ ni; nitori pe ko si ẹni ti o le mu daadaa wa afi Ọlọhun, ko si si ẹni ti o le ti aburu danu afi Ọlọhun nikan ṣoṣo ti ko si orogun fun Un. Ọmọ Mas'ud- ki Ọlọhun yọnu si i- sọ pe nnkan kan ninu ifuramọ aburu le waye ninu ọkan Musulumi, ṣùgbọ́n o jẹ dandan fun un lati fi igbarale Ọlọ́hun ti i danu, pẹlu ṣíṣe awọn okunfa.

Hadeeth benefits

  1. Fifi ẹyẹ furamọ aburu ati oore ẹbọ ni; nitori pe isopọ ọkan pẹlu ẹni ti o yàtọ̀ si Ọlọhun n bẹ nibẹ.
  2. Pataki pipaara awọn ibeere ti wọn ṣe koko, ki wọn le ha wọn ki o si lee rinlẹ ninu awọn ọkan.
  3. Igbarale ọlọhun- ti ọla Rẹ ga- maa n mu fifi ẹyẹ furamọ aburu ati oore lọ.
  4. Pipaṣẹ igbarale Ọlọhun nikan ṣoṣo ati siso ọkan pọ mọ Ọn- mimọ ni fun Un-.