- Ṣiṣọ taohid ati adisọkan kúrò nibi nǹkan ti o maa ba a jẹ́.
- Ṣíṣe lilo ọfọ ti ẹlẹbọ ati àsokọ́ra ati oogun ifẹran ni eewọ.
- Adisọkan ọmọniyan nipa awọn mẹtẹẹta yii pe okùnfà ni wọn: Oun ni ẹbọ kekere; torí pé o ṣe ohun ti kii ṣe okùnfà ni okùnfà, ṣùgbọ́n ti o ba ni adisọkan pe oun ni yoo ṣe anfaani tabi fa inira funra rẹ, ìyẹn ni ẹbọ ńlá.
- Ikilọ kuro nibi ṣíṣe àwọn òkùnfà ti ẹlẹbọ ati eyi ti o jẹ eewọ.
- Ṣíṣe ọfọ ni eewọ, ati pe ẹbọ ni, ayafi eyi ti o ba ba sharia mu.
- O tọ́ ki ọkàn rọ̀ mọ́ Ọlọhun nìkan, ọdọ Rẹ ni ìnira ati àǹfààní ti n wa, ko ni orogun, ko si ẹni ti o le mu oore wa ayafi Ọlọhun, ko si si ẹni ti o le ti aburu lọ ayafi Ọlọhun.
- Ọfọ ti o tọ́ ni eyi ti o ko májẹ̀mú mẹta sinu:
- 1- Ki a ni adisọkan pe okùnfà ni wọn, wọn ko lee ṣe anfaani ayafi pẹ̀lú iyọnda Ọlọhun.
- 2- Ki wọn jẹ pẹlu Kuraani ati awọn orukọ Ọlọhun ati awọn iroyin Rẹ, ati awọn adua ti Anọbi, ati awọn adua ti wọn ba sharia mu.
- 3- Ki wọn jẹ pẹlu èdè ti a gbọye, ti ko si nii ni ìwé oògùn ati ẹtan ninu.