- Hadīth yii ninu awọn ti Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - gba wa lati ọdọ Oluwa rẹ ni, ti wọn si maa n pe é ni Hadīth Al-Qudusiy tabi Al-Ilaahiy, oun si ni eyi ti o ṣe pe gbolohun rẹ ati itumọ rẹ wa lati ọdọ Ọlọhun, yatọ si pe ko ni awọn ìròyìn ẹsa Alukuraani ti o fi da yatọ si awọn miran, bii mimaa jọsin pẹlu kika rẹ ati ṣiṣe imọra fún un, ati ipenija ati idalagara, ati èyí tí o yàtọ̀ si i.
- Kikọ kuro nibi fifi ṣuta kan awọn aayo Ọlọhun ati ṣiṣenilojukokoro síbi ninifẹẹ wọn, ati fifi ọla wọn rinlẹ.
- Pipa àṣẹ pẹlu biba awọn ọta Ọlọhun ṣe ọta ati ṣíṣe ìní ìfẹ́ wọn ni eewọ.
- Ẹni ti o ba pe apemọra ijẹ aayo Ọlọhun lai tẹle ofin Rẹ, opurọ ni in nibi apemọra rẹ.
- Ọwọ a maa tẹ jijẹ aayo Ọlọhun pẹlu ṣiṣe awọn ọranyan ati gbigbe awọn eewọ jusilẹ.
- Ninu awọn okunfa ifẹ Ọlọhun si ẹru Rẹ ati jijẹ ipe adua rẹ ni ṣiṣe awọn aṣegbọrẹ lẹyin ṣiṣe awọn ọranyan ati gbigbe awọn eewọ jusilẹ.
- Ẹri lori iyi awọn aayo Ọlọhun ati giga ipo wọn.