Àlàyé
Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ṣe waasu kan ti o de ogongo fun awọn saabe, ti awọn ọkan gbọn ti awọn oju dami latara rẹ, Wọn sọ pe: Irẹ ojiṣẹ Ọlọhun o da gẹgẹ bii waasu idagbere fun nnkan ti wọn ri ninu wiwọnu rẹ- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- nibi waasu náà, wọn wa beere fun àsọtẹ́lẹ̀ ki wọn le gba a mu lẹyin rẹ, O sọ pe: Mo n sọ àsọtẹ́lẹ̀ fun yin pẹlu ibẹru Ọlọhun- Alagbara ti O gbọnngbọn-, ìyẹn maa rí bẹ́ẹ̀ pẹlu ṣíṣe awọn nnkan ti wọn jẹ dandan ati gbigbe awọn eewọ ju silẹ, Ati gbigbọ ati itẹle, o n túmọ̀ si: Fun awọn adari, ko da ki ẹru jẹ adari fun yin, o n túmọ̀ si ki ẹni ti o kere julọ ninu ẹda di adari le yin lori, ẹ ko gbọdọ kọ ìyẹn, ki ẹ si tẹle e, ni ti ipaya dídá fitina sílẹ̀, dajudaju ẹni ti o ba ṣẹmi ninu yin maa pada ri iyapa ti o pọ, Lẹyin naa o ṣàlàyé ọna àbáyọ fun wọn kuro nibi iyapa yìí, ìyẹn pẹlu gbigba sunnah rẹ mu ati sunnah awọn arole ẹni imọna ti a fi ọna mọ wọn lẹyin rẹ, Abu Bakr, ati Umar ọmọ Khattaab, ati Uthman ọmọ 'Affan, ati Aliy ọmọ Abu Toolib- ki Ọlọhun yọnu si wọn lapapọ-, ati gbigba a mu pẹlu ẹyin ọgan, o n túmọ̀ si- awọn ẹyin ẹgbẹ ti o kẹ́yìn-: O n túmọ̀ ẹyin ọgan yẹn si didunnimọ sunnah daada ati didirọmọ ọn, O ṣe ikilọ fun wọn kuro nibi awọn alamọri ti a da wọn silẹ sinu ẹsin, ati pe dajudaju gbogbo adadaalẹ anu ni.