- Kikọ ibajẹ ni asiko riri rẹ ati aima lọra nibi ìyẹn, nigba ti ko ba si aburu nla ti o ju ìyẹn lọ nibẹ.
- Iya ni ọjọ igbedide maa yatọ nibamu si titobi ẹṣẹ.
- Yiya aworan awọn abẹmi wa ninu awọn ẹṣẹ ti wọn tobi julọ.
- Ninu ọgbọ́n ti o n bẹ nibi ṣíṣe leewọ yiya aworan ni afijọ ẹda Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga- boya oluyaworan gbero afijọ tabi ko gbero rẹ.
- Ojúkòkòrò sharia lori sisọ awọn dukia pẹlu ṣíṣe anfaani latara rẹ lẹyin gbigbe e jina si nnkan ti wọn ṣe leewọ nibẹ.
- Kikọ kuro nibi ṣíṣe awọn aworan abẹmi lori èyíkéyìí ìrísí ti o le jẹ, koda ki o jẹ ìyílẹ̀.