/ Ọlọhun kọ kadara awọn ẹda ṣíwájú ki O to da sanmọ ati ilẹ fun ẹgbẹrun lọ́nà aadọta ọdun

Ọlọhun kọ kadara awọn ẹda ṣíwájú ki O to da sanmọ ati ilẹ fun ẹgbẹrun lọ́nà aadọta ọdun

Lati ọdọ Abdullahi ọmọ Amru ọmọ ‘Aas- ki Ọlọhun yọnu si awọn mejeeji- o sọ pe: Mo gbọ́ ti ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n sọ pé: "Ọlọhun kọ kadara awọn ẹda ṣíwájú ki O to da sanmọ ati ilẹ fun ẹgbẹrun lọ́nà aadọta ọdun, o sọ pe: Aga ọla Rẹ wa ni ori omi".
Muslim gba a wa

Àlàyé

Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pe dajudaju Ọlọhun kọ nnkan ti o maa ṣẹlẹ̀ ninu awọn kadara awọn ẹda ni ifọsiwẹwẹ ninu isẹmi ati iku ati arisiki ati nnkan ti o yatọ si ìyẹn sinu Wàláà ti A n ṣọ ṣíwájú ki O to da sanmọ ati ilẹ fun ẹgbẹrun lọ́nà aadọta ọdun, ti yoo maa ṣẹlẹ̀ ni ibamu si nnkan ti Ọlọhun- Alagbara ti O gbọnngbọn- ti kadara, Gbogbo nnkan ti o n bẹ n bẹ pẹlu idajọ Ọlọhun ati kadara Rẹ, Nnkan ti o ba ṣẹlẹ̀ si ẹru wọn ti kọ ọ pe ko nii fo o ru, nnkan ti o ba fo o ru wọn ti kọ ọ pe ko nii ṣẹlẹ̀ si i ni.

Hadeeth benefits

  1. Jijẹ dandan nini igbagbọ ninu idajọ ati kadara.
  2. Kadara ni: Imọ Ọlọhun nipa gbogbo nnkan ati kikọ wọn Rẹ ati fifẹ Rẹ ati dida Rẹ ti O da wọn.
  3. Nini igbagbọ pe awọn kadara jẹ nnkan ti wọn kọ ṣíwájú dida sanmọ ati ilẹ, ìgbàgbọ́ yii maa ṣeso iyọnu ati jijupa-jusẹ silẹ.
  4. Dajudaju aga ọla Ọba Ajọkẹ-aye wa lori omi ṣíwájú dida sanmọ ati ilẹ.