- Ninu awọn okunfa tí eniyan fi n kó sínú ifẹkufẹẹ adun aye ni kí èṣù kó ọ̀ṣọ́ bá awọn nkan naa, tí ó jẹ́ nkan buruku tí kò dara, títí eniyan o fi ri i pé ó dara, yoo sì ṣẹ́rí lọ si idi rẹ̀.
- Àṣẹ jíjìnà sí awọn adùn aye tó jẹ́ eewọ; nitori pe ọ̀nà ati wọ iná ni, ati ṣiṣe suuru lori awọn nkan tí ẹmi wa koriira rẹ̀; nitori pe ọ̀nà ati wọ Alujanna ni.
- Ọlá tí n bẹ fún jija ẹ̀mí ara ẹni lógun, ati gbígbìyànjú nibi ijọsin fun Ọlọhun, ati níní suuru lori awọn nnkan ti èèyàn koriira ati inira tí ó wà níbi titẹle ti Ọlọhun.