Àlàyé
Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pe dajudaju Ọlọhun, nigba ti O da alujanna ati ina, O sọ fun Jibril- ki ikẹ Ọlọhun maa ba a- pé: Lọ si alujanna ki o si wo o, bayii ni o ṣe lọ, o si wo o, lẹyin naa o ṣẹri pada, Jubril si sọ pé: Irẹ Oluwa mi, mo fi agbara Rẹ bura ẹnikẹni ko nii gbọ́ nipa rẹ ati nipa nnkan ti o n bẹ nibẹ ninu idẹra ati awọn oore afi ko fẹ lati wọ ọ, ki o si maa ṣe iṣẹ́ nitori rẹ. Lẹyin naa Ọlọhun wa fi awọn nnkan ti ẹmi korira ati awọn nǹkan ti ó le rọkirika alujanna bii ṣíṣe awọn nnkan ti wọn pa wa láṣẹ ati jijina si awọn nnkan ti wọn kọ̀; o wa jẹ dandan fun ẹni ti o ba fẹ wọ ọ lati re kọja awọn nnkan ti ẹmi korira yẹn. Lẹyin naa Ọlọhun- Alagbara ti O gbọnngbọn- sọ pé: Irẹ Jibril! Lọ ki o lọ wo alujanna, lẹyin igba ti O rọkirika rẹ pẹlu awọn nnkan ti ènìyàn korira, O si lọ wo o, lẹyin naa o sọ pe: Irẹ Oluwa mi, mo fi agbara Rẹ bura, mo n paya ki ẹnikẹni ma wọ ọ pẹlu okunfa awọn ilekoko ati awọn wahala ti wọn wa ni oju ọna rẹ. Nígbà ti Ọlọhun da ina, O sọ pe: Irẹ Jibril! Lọ ki o lọ wo o, o si lọ wo o, Lẹyin naa ni o dé, Jibril wa sọ pé: Irẹ Oluwa mi, mo fi agbara Rẹ bura, ẹnikẹni ko nii gbọ́ nipa iya ati awọn wahala ati ìfìyàjẹ ti o wa nínú rẹ̀ afi ki o korira lati wọ ọ ki o sì jina si awọn okunfa rẹ. Lẹyin naa Ọlọhun- Alagbara ti O gbọnngbọn- fi àwọn adùn rọkirika ina, O si ṣe wọn ni oju ọna lọ si ibẹ, lẹyin naa, O sọ pe: Irẹ Jibril, lọ ki o si wo o, Jibril si lọ o si wo o, lẹyin naa o de, o si sọ pe: Irẹ Oluwa mi, mo fi agbara Rẹ bura, dajudaju mo paya ẹru si ba mi pe ki ẹni kankan ma la kuro nibẹ; fun nnkan ti o rọkirika rẹ ninu awọn adun.