Abàtà mi, ìrìn oṣù kan ni, omi rẹ̀ funfun ju wàrà lọ, òórùn rẹ̀ dùn ju alumisiki lọ
Lati ọdọ Abdullah ọmọ Amr, ki Olohun yọnu si awọn mejeeji, o sọ pe: Anabi, ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a, sọ pe: Abàtà mi, ìrìn oṣù kan ni, omi rẹ̀ funfun ju wàrà lọ, òórùn rẹ̀ dùn ju alumisiki lọ , ife rẹ̀ sì dà bii ìràwọ̀ ojú ọ̀run, ẹni tí ó bá mu nínú ẹ, òùngbẹ kò nii gbẹ ẹ́ láéláé.”
Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí ni
Àlàyé
Anabi, ki ikẹ ati ọla Ọlọhun o maa ba a, sọ pe oun yoo ni abàtà kan ni Ọjọ Ajinde, ti òró rẹ yoo jẹ irin oṣu kan, ti ìbú rẹ naa si maa jẹ irin oṣù kan, Omi rẹ funfun ju wara lọ, Oorun rẹ dun ju ti alumisiki lọ, Àwọn àgé omi rẹ̀ pọ̀ bíi ìràwọ̀ ojú ọ̀run, Ẹnikẹ́ni tí ó bá fi àgé omi náà mu omi ninu abata naa, òùngbẹ kì yóò gbẹ ẹ́ mọ́ láéláé.
Hadeeth benefits
Abata ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a- jẹ ibi ti omi kó jọ si ti o tóbi ti àwọn onigbagbọ ninu ijọ rẹ maa wa síbẹ̀ ni ọjọ́ alukiyaamọ.
Ṣiṣẹlẹ igbadun fun ẹni ti o ba mu ninu abata naa, òùngbẹ ko nii gbẹ ẹ mọ láéláé.
Share
Use the QR code to easily share the message of Islam with others