Ọlọhun a gba ilẹ mu, yoo si tun ka sanmọ pẹlu ọwọ ọtun Rẹ, lẹyin naa ni Yoo waa sọ pe: Emi ni Ọba, gbogbo ọba (olukapa) ori ilẹ̀ da?
Lati ọdọ Abu Hurayra - ki Ọlọhun yọnu si i - o sọ pe: Mo gbọ ti ojiṣẹ Ọlọhun - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - n sọ pe: «Ọlọhun a gba ilẹ mu, yoo si tun ka sanmọ pẹlu ọwọ ọtun Rẹ, lẹyin naa ni Yoo waa sọ pe: Emi ni Ọba, gbogbo ọba (olukapa) ori ilẹ̀ da?».
Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí ni
Àlàyé
Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - fúnni niroo nipa pe dajudaju Ọlọhun ti ọla Rẹ ga Yio gba ilẹ mu ni ijọ igbende ti yio si pa a pọ, ati pe yio ka sanmọ pẹlu ọwọ ọtun Rẹ ti Yio si ka a lori ara wọn tii Yio si pa a rẹ, lẹyin naa ni Yio wa sọ pe: Emi ni Ọba, gbogbo ọba (olukapa) orilẹ da?!
Hadeeth benefits
Irannileti pe ọlá Ọlọhun ni yio maa sẹku ati pe ọlá ẹni ti o yatọ si I nkan ti yio yẹ ni.
Gbigbọnngbọn Ọlọhun ati titobi ikapa Rẹ ati agbára Rẹ ati pipe ọla Rẹ.
Share
Use the QR code to easily share the message of Islam with others