Anabi – ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a – jẹ ẹni ti maa n ṣe aluwala fun gbogbo irun
Lati ọdọ ‘Amru ọmọ ‘Aamir lati ọdọ Anas ọmọ Mālik o sọ pe: Anabi – ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a – jẹ ẹni ti maa n ṣe aluwala fun gbogbo irun, mo wa sọ pe: Bawo ni ẹyin ṣe maa n ṣe? O sọ pe: Aluwala ẹyọkan maa n to fun ẹnikẹni ninu wa lopin igba ti ko ba ti dá ẹgbin.
Bukhaariy gba a wa
Àlàyé
Anabi – ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a – jẹ ẹni ti maa n ṣe aluwala fun gbogbo irun ọranyan koda ki aluwala rẹ o ma bajẹ; iyẹn ni lati fi gba ẹsan ati ọla.
O si tun lẹtọọ ki o ki ju irun ọranyan ẹyọkan lọ pẹlu aluwala ẹyọkan lopin igba ti o ba ṣi ni aluwala.
Hadeeth benefits
Eyi ti o pọju ninu iṣe Anabi – ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a – oun ni ṣiṣe aluwala fun gbogbo irun; lati fi wa eyi ti o pe julọ.
Nǹkan ti a fẹ ni ṣíṣe aluwala fun gbogbo irun.
Lilẹtọọ kiki irun ti o pọ ju ẹyọkan lọ pẹlu aluwala ẹyọkan.
Share
Use the QR code to easily share the message of Islam with others