- Ọla ti o n bẹ fun Aliy ọmọ Abu Toolib- ki Ọlọhun yọnu si i-, nigba ti itiju ko kọdi rẹ nibi gbigbe ibeere ju silẹ pẹlu alagata.
- Nini ẹtọ yiyan ẹni kan lati lọ ba eeyan beere idajọ ẹsin.
- Nini ẹtọ sísọ fun ọmọniyan nipa ara rẹ pẹlu nnkan ti o ba n ti i loju fun anfaani.
- Jijẹ ẹgbin atọ ireke, ati jijẹ dandan fifọ ọ kuro ni ara ati aṣọ.
- Jijade atọ ireke wa ninu awọn nnkan ti n ba aluwala jẹ.
- Jijẹ dandan fifọ nnkan ọmọkunrin ati koropọn mejeeji nitori wiwa rẹ ninu hadiisi mii.