Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - jẹ ẹni ti o ṣe pe ti o ba fẹ wọ aaye ẹgbin yio sọ pe: «Allaahummọ inni a‘uudhu biKa minal khubuthi wal khabaaithi
Lati ọdọ Anas - ki Ọlọhun yọnu si i - o sọ pe: Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - jẹ ẹni ti o ṣe pe ti o ba fẹ wọ aaye ẹgbin yio sọ pe: «Allaahummọ inni a‘uudhu biKa minal khubuthi wal khabaaithi».
Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí ni
Àlàyé
Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - jẹ ẹni ti o ṣe pe ti o ba fẹ wọ aaye ti yio ti biiya bukaata rẹ, itọ tabi igbẹ, yio wa iṣọra pẹlu Ọlọhun, yio si tun sa di I ki O la a nibi aburo awọn eṣu ni takọ tabi tabo. Wọn si tu al-khubuthi ati al-khabaaith sí aburu ati awọn ẹgbin.
Hadeeth benefits
Ṣiṣe ni sunnah ṣiṣe adua yii nigba ti a ba gbero wiwọ ile ẹgbin.
Gbogbo ẹda ni wọn bukaata si Oluwa wọn nibi titi nkan ti o le ṣe wọn ni ṣuta tabi ko inira ba wọn danu nibi gbogbo ìṣesí wọn.
Share
Use the QR code to easily share the message of Islam with others