- Àwọn sunnah awọn ojiṣẹ ti Ọlọhun nífẹ̀ẹ́ si wọn ti O si yọnu si wọn ti O si pa wa láṣẹ pẹlu wọn, wọn n pepe lọ si ibi pipe ati mimọ ati ẹwa.
- Ṣíṣe àwọn nǹkan yii láti ìgbà dégbà jẹ nnkan ti wọn ṣe lofin, ti a ko si gbọdọ gbàgbé wọn.
- Àwọn anfaani ti aye ati ti ọrun n bẹ fun awọn iwa yìí, ninu wọn ni: Titun ìrísí ṣe, ati mimọ ara, ati pipalẹmọ fun imọra, ati yiyatọ si awọn alaigbagbọ, ati mimu àṣẹ Ọlọhun ṣẹ.
- Wọn darukọ alekun awọn iwa naa ti wọn yatọ si awọn maraarun-un yii ninu awọn hadiisi miran, gẹgẹ bii: Dida irùngbọ̀n sì, ati rirun pako, ati eyi ti o yatọ si wọn.