- Iwẹ iran meji ni: Eyiti o toni ati eyiti o pe, ẹẹ wa ri iwẹ ti o toni, ọmọnìyàn o da aniyan imọra, lẹyin naa yio fi omi kari gbogbo ara rẹ pẹlu fifi omi yọ ẹnu ati fifin omi si imu, ṣugbọn iwẹ ti o pe, yio wẹ gẹgẹ bi Anabi ṣe wẹ ninu hadīth yii.
- Wọn maa n lo Janaba fun gbogbo ẹni ti o ba da atọ si ara, tabi ti o ba ni ibalopọ koda ki o ma da atọ.
- Jijẹ ẹtọ ki ọkọ ati iyawo o maa wo ihoho ara wọn, ati ki wọn maa wẹ papọ ninu igba kan naa.