- Hadīth yii ipilẹ kan ni ninu awọn ipilẹ Isilaamu, o tun jẹ òfin kan ninu awọn ofin agbọye ẹsin, oun ni pe: Dajudaju amọdaju ko lee yẹ pẹlu iyemeji, ati pe ipilẹ ni wiwa nkan ti o n bẹ lori ohun ti o n bẹ lori rẹ, titi ti nkan ti o yatọ si iyẹn fi maa daju.
- Iyemeji o ki n lapa nibi imọra, ati pe ẹni ti n kirun si wa lori imọra rẹ lopin igba ti ko ba tii ni amọdaju ẹgbin.