/ Ti ẹ ba ti gbọ oluperun ki ẹ yaa maa sọ gẹgẹ bi o ṣe n sọ, lẹyin naa ki ẹ wa ṣe asalaatu fun mi

Ti ẹ ba ti gbọ oluperun ki ẹ yaa maa sọ gẹgẹ bi o ṣe n sọ, lẹyin naa ki ẹ wa ṣe asalaatu fun mi

Lati ọdọ Abdullāh ọmọ ‘Amru ọmọ al-‘Aas – ki Ọlọhun yọnu si i – dajudaju o gbọ ti Anabi – ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a – n sọ pe: «Ti ẹ ba ti gbọ oluperun ki ẹ yaa maa sọ gẹgẹ bi o ṣe n sọ, lẹyin naa ki ẹ wa ṣe asalaatu fun mi, torí pé dajudaju ẹni ti o ba ṣe asalaatu kan fun mi Ọlọhun a fi ṣe mewaa fun un, lẹyin naa ki ẹ beere al-Wasiilah fun mi lọdọ Ọlọhun, ati pe dajudaju oun ni ipo kan ninu al-jannah, ti ko si lẹtọọ ayaafi fun ẹru kan ninu awọn ẹru Ọlọhun, mo si fẹ ki o jẹ emi, nitori naa ẹni ti o ba beere al-Wasiilah fun mi iṣipẹ ti di ẹtọ fun un».
Muslim gba a wa

Àlàyé

Anabi – ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a – juwe ẹni ti o ba gbọ oluperun lọ sibi pe ki o maa sọ tẹle e nǹkan ti o ba n wi, nitori naa yio maa sọ iru ọrọ rẹ (oluperun), yatọ si Hayya‘ala mejeeji (Hayya‘alas sọlaah ati Hayya‘alal falaah), yio sọ lẹyin mejeeji pe: Laa haola walā quwwata illā biLlāh, lẹyin naa yio ṣe asalaatu fun Anabi – ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a – lẹyin ti o ba pari irun pipe, torí pé dajudaju ẹni ti o ba ṣe asalaatu kan Ọlọhun a titori rẹ ṣe asalaatu mẹwaa fun un, ati pe itumọ asalaatu Ọlọhun fun ẹru Rẹ ni: Ẹyin Rẹ fun ẹru Rẹ lọdọ awọn malaaika. Lẹyin naa ni o wa paṣẹ pẹlu bibi Ọlọhun leere al-Wasiilah fun oun– ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a -, ati pe oun (al-Wasiilah) naa ni ipo kan ninu al-jannah, ati pe oun lo ga jùlọ ninu rẹ, ko si lẹtọọ bẹẹ ni ko rọrun ayaafi fun ọkan ninu gbogbo awọn ẹru Ọlọhun ti ọla Rẹ ga, ti mo si n tanmọọn ki n jẹ ẹni naa, ati pe o sọ iyẹn – ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a – ni ti itẹriba; torí pé dajudaju ti ipo giga yẹn o ba nii wa ayaafi fun ẹnikan, ko wa si ẹni ti o lẹ jẹ ẹnikan yẹn ayaafi oun – ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a -; torí pé oun ni o lọla julọ ninu awọn ẹda. Lẹyin naa o – ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - wa ṣe alaye pe dajudaju ẹni ti o ba ṣe adua al-Wasiilah fun Anabi – ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a – iṣipẹ rẹ - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a – a jẹ tiẹ.

Hadeeth benefits

  1. Ṣiṣenilojukokoro lori ijẹpe oluperun (sisọ gẹgẹ bi oluperun ṣe sọ).
  2. Ọla ti n bẹ fun ṣiṣe asalaatu fun Anabi – ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a – lẹyin ijẹpe oluperun (sisọ gẹgẹ bi oluperun ṣe sọ).
  3. Ṣiṣenilojukokoro lori bibeere al-Wasiilah fun Anabi – ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a – lẹyin ṣiṣe asalaatu fun un.
  4. Alaye itumọ al-Wasiilah, ati giga ipo rẹ, latari pe ko lẹtọọ ayaafi fun ẹru kan.
  5. Alaye ọla Anabi – ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a – latari pe wọn ṣe ipo ti o ga yẹn ni ẹsa fun un.
  6. Ẹni ti o ba beere al-Wasiilah ni ọwọ Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga- fún Anabi – ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a – iṣipẹ rẹ (Anabi) ti di ẹtọ fun un.
  7. Alaye itẹriba rẹ - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a – latari pe o wa lati ọdọ awọn ijọ rẹ ki wọn ṣe adua fun un pẹlu ipo yẹn, toun ti pe dajudaju ti ẹ naa ni yio jẹ.
  8. Gbigbaaye ọla Ọlọhun ati ikẹ Rẹ, nitori naa iṣẹ rere kan ilọpo mẹwaa iru rẹ ni ẹsan rẹ.