- Irun jẹ ipa ẹṣẹ rẹ fun awọn ẹṣẹ, oun ni eyi ti ẹru ba ṣe aluwala rẹ daadaa, ti o si ki i ni olupaya ti o fi wa oju rere Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga-.
- Ọla ti o n bẹ fun idunnimọ awọn ijọsin, ati pe o jẹ okunfa fun aforijin awọn ti wọn kere ninu awọn ẹṣẹ.
- Ọla ti o n bẹ fun ṣíṣe aluwala daadaa, ati kiki irun daadaa ati nini ipaya nibẹ.
- Pataki jijina si awọn ti o tobi ninu awọn ẹṣẹ lati ṣe aforijin àwọn ẹ̀ṣẹ̀ kéékèèké.
- Awọn ẹṣẹ ńláńlá ko ṣee parẹ afi pẹlu ironupiwada.