- Jijẹ dandan iwẹ fun obinrin nigba ti awọn ọjọ nkan oṣu rẹ ba pari.
- Jijẹ dandan irun fun ẹni ti n ri ẹjẹ awaada.
- Al-haydu ni: Ẹjẹ adamọ ti apo ibimọ maa n ti i jade lati ibi abẹ obinrin ti o ti di ẹni ọkunrin, eleyii ti yio maa ṣẹlẹ si i ni awọn ọjọ ti a ti mọ.
- Al-Istihaadoh ni: Sisan ẹjẹ ni igba ti kii ṣe asiko rẹ lati ẹnu apo ibimọ lai de ọgun rẹ.
- Iyatọ ti o wa laarin ẹjẹ nkan oṣu ati ẹjẹ awaada ni pe: Dajudaju ẹjẹ nkan oṣu dudu ti o ki ti oorun rẹ o si tun daa, amọ ẹjẹ awaada pupa ti o ṣàn ni ti ko si si oorun ti ko daa fun un.