- Ti ẹni ti n kirun ba ṣe iyemeji ninu irun rẹ ti ikankan ninu alamọri mejeeji o si leke ni ọdọ rẹ, dajudaju ni igba naa yio ti iyemeji danu ti yio si ṣe amulo amọdaju, oun naa ni eyi ti o kere ju, nitori naa yio pe irun rẹ yio si fi ori kanlẹ fun igbagbe ṣaaju ki o to salamọ lẹyin naa yio wa salamọ.
- Iforikanlẹ mejeeji yii jẹ ọna lati tun irun ṣe, o tun jẹ dida èṣù pada ni ẹni yẹpẹrẹ ti wọn gbe jìnnà si erongba rẹ̀.
- Iyemeji ti o wa ninu hadīth yii oun ni iyemeji laisi pe ọkan tẹsunwọn ju ọkan lọ, ti a ba wa ri èrò ti o tẹsunwọn, a maa lo o.
- Ṣiṣenilojukokoro lori gbigbe ogun ti royiroyi ati titi i danu pẹlu titẹle aṣẹ ofin (Ọlọhun).