“ko si irun pẹlu ikalẹ ounjẹ, tabi nigba ti igbẹ ati itọ ba n gbọ̀n ọ́n”
Lati ọdọ ‘Aaisha- ki Ọlọhun yọnu si i- o sọ pe: Dajudaju mo gbọ́ ti ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n sọ pe: “ko si irun pẹlu ikalẹ ounjẹ, tabi nigba ti igbẹ ati itọ ba n gbọ̀n ọ́n”.
Muslim gba a wa
Àlàyé
Ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- kọ kuro nibi kiki irun pẹlu ikalẹ ounjẹ ti ẹmi olukirun n fa síbẹ̀, ti ọkan rẹ si n so mọ ọn.
Gẹgẹ bẹẹ ni o ṣe kọ kuro nibi kiki irun pẹlu dídá Al-Akhbathaan- awọn mejeeji ni itọ ati igbẹ- padà, nitori kiko airoju rẹ pẹlu dídá ẹgbin náà padà.
Hadeeth benefits
O tọ fun olukirun lati gbé gbogbo nnkan ti o le maa ko airoju ba a nibi irun rẹ jìnnà ṣíwájú ki o to wọnu rẹ.
Share
Use the QR code to easily share the message of Islam with others