- Aburu imaa fa sẹyin nibi kiki irun janmọọn ninu masalaasi.
- Awọn munaafiki o gbero pẹlu irun wọn ayaafi ṣekarini ati ṣekagbọni, nitori naa wọn ko nii wa ki irun ayaafi ni igba ti awọn eeyan maa ri wọn.
- Titobi ẹsan ti n bẹ nibi kiki irun Ishai ati Asunbaa pẹlu janmọọn, ati pe awọn mejeeji lẹtọọ si imaa wa ki wọn koda ko jẹ pẹlu rirakoro.
- Imaa ṣọ irun Ishai ati irun Asunbaa, lila lo jẹ kuro nibi jíjẹ́ munaafiki, ati pe imaa fa sẹyin nibi mejeeji ninu iroyin awọn munaafiki lo wa.