Dajudaju Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- maa n sọ laaarin iforikanlẹ mejeeji pé: Robbi igfir liy, Robbi igfir liy”
Lati ọdọ Huzeifah- ki Ọlọhun yọnu si i-: Dajudaju Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- maa n sọ laaarin iforikanlẹ mejeeji pé: Robbi igfir liy, Robbi igfir liy”.
Abu Daud ati Nasaa'iy ati Ibnu Maajah ati Ahmad ni wọ́n gba a wa
Àlàyé
Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- maa n sọ nibi ijokoo laaarin iforikanlẹ mejeeji pé: Robbi igfir liy, Robbi igfir liy, o si maa n paara rẹ.
Ìtumọ̀ Robbi igfir liy ni pé: Ki ẹru wa lati ọdọ Oluwa rẹ lati pa awọn ẹṣẹ rẹ rẹ ki O si bo awọn aleebu rẹ.