Àlàyé
Saabe ti o n jẹ Abu Musa Al-Ash'ariy- ki Ọlọhun yọnu si i- kirun kan, nigba ti o wa ni ijokoo ti ataya wa nibẹ, arakunrin kan ninu awọn ti wọn kirun lẹyin rẹ sọ pe: Wọn da irun pọ mọ daadaa ati saka ninu Kuraani, nigba ti Abu Musa- ki Ọlọhun yọnu si i- kirun tan, o doju kọ awọn ero ẹyin, ni o wa bi wọn leere pé: Ewo ninu yin lo sọ gbolohun: Wọn da irun pọ mọ daadaa ati saka ninu Kuraani?! Ni awọn èèyàn ba dakẹ, ti ẹnikẹni ko sọ̀rọ̀ ninu wọn, ni o ba paara ibeere naa lẹẹkan si, nigba ti ẹnikẹni ko da a lohun, Abu Musa- ki Ọlọhun yọnu si i- sọ pe: Boya iwọ Hittọọn ni o sọ ọ! Nitori ìgboyà rẹ ati asunmọ rẹ ati asopọ rẹ pẹlu rẹ, ninu nnkan ti kikẹfin rẹ ko lee ko suta ba a, ati pe ki o le ti ẹni ti o ṣe e gangan jade lati jẹwọ, ni Hittọọn wa sọ pe ko ri bẹ́ẹ̀, o wa sọ pe: Mo bẹru ki o ma bu mi ti o n lero pe emi ni mo sọ ọ; ibi yii ni arakunrin kan ti sọ ninu awọn ijọ pe: Emi ni mo sọ ọ, mi ko si gbero nnkan kan pẹlu rẹ afi dáadáa, ni Abu Musa wa sọ ni ẹni ti o n kọ ọ pé: Ṣe ẹ ko mọ bi ẹ ṣe ma maa sọ lori irun yin ni?! Eleyii jẹ àtakò lati ọdọ rẹ, lẹyin naa Abu Musa wa sọ pe dajudaju Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ba awọn sọ̀rọ̀ ni ọjọ kan, ti o ṣàlàyé Sharia wọn fun wọn, ti o kọ wọn ni irun wọn, ni Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- wa sọ pé:
Ti ẹ ba fẹ kirun, ki ẹ ya gbe saafu dide ki ẹ si duro tọ́ nibẹ, lẹyin naa ki ẹnikan ninu wọn ṣe imaamu fun awọn eniyan, ti imaamu ba ti kabara wiwọ inu irun, ki ẹyin naa kabara iru rẹ, ti o ba ti ka Fatiha ti o ba wa de: ((Ghayril-maghdoobi ‘alaihim wa lad-daaalleen) (Al- Fatiha: 7)), ki ẹ sọ pe: Aamiin; ti ẹ ba ṣe bẹẹ Ọlọhun maa gba adura yin, ti o ba kabara ti o si rukuu, ki ẹyin naa kabara ki ẹ si rukuu; dajudaju imaamu maa rukuu ṣíwájú yín o si maa gbe ori dide ṣíwájú yín, nitori naa ẹ ko gbọdọ ṣíwájú rẹ; nitori pe asiko ti imaamu gba waju nibẹ lati ṣíwájú yin rukuu, ilọra yin ni rukuu lẹyin ti imaamu ti gbori kuro maa di i fun yin, iru asiko yẹn pẹlu asiko yẹn, odiwọn rukuu yin maa da gẹgẹ bii odiwọn rukuu rẹ, ti imaamu ba sọ pe: Sami'alloohu liman hamidaHu, ki ẹ sọ pé: Allahumo Robbanaa wa laKal hamdu, ti awọn ero ẹyin ba sọ ìyẹn, dajudaju Ọlọhun- mimọ ni fun Un- maa gbọ́ adura wọn ati ọrọ wọn, nitori pe Ọlọhun- ibukun ni fun orúkọ Rẹ, ti ọla Rẹ ga- sọ lori ahọn Anabi Rẹ- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- pé: Samihal Loohu liman hamidaHu, lẹyin naa ti imaamu ba kabara ti o si forikanlẹ, o jẹ dandan fun awọn ero ẹyin lati kabara ki wọn si forikanlẹ, dajudaju imaamu maa forikanlẹ ṣíwájú wọn, o si maa gbe ori dide ṣíwájú wọn, iru asiko yẹn pẹlu asiko yẹn, odiwọn iforikanlẹ ero ẹyin maa da gẹgẹ bii odiwọn iforikanlẹ imaamu, ti o ba wa lori ijokoo ataya, ki akọkọ ọrọ olukirun jẹ: At-tahiyyaatu toyyibaatus solawaatu lillah"
Ọla ati ṣiṣẹku ati titobi gbogbo rẹ pata jẹ ẹtọ fun Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga-, gẹgẹ bẹ́ẹ̀ naa ni awọn irun maraarun-un, gbogbo rẹ pata jẹ ti Ọlọhun, "As-salaamu 'alayka ayyuhan nabiyyu wa rahmatullah wa barokaatuhu, as-salaamu 'alayna wa 'alaa 'ibaadillahis soliheen", ẹ pe Ọlọhun fun lila kuro nibi gbogbo aleebu ati adinku ati ibajẹ; a maa ṣẹsa Anabi wa Muhammad- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- pẹlu àlàáfíà, lẹyin naa a maa tọrọ alaafia fun ara wa, lẹyin naa a maa tọrọ alaafia fun awọn ẹru Ọlọhun ti wọn jẹ ẹni rere ti wọn ṣe nnkan ti o jẹ dandan fun wọn ninu awọn iwọ Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga- ati awọn iwọ awọn ẹru Rẹ, lẹyin naa, a maa jẹrii pe ko si ẹni ti ijọsin tọ si lododo afi Ọlọhun, a si n jẹrii pe dajudaju Muhammad ẹru Rẹ ni ati ojiṣẹ Rẹ.