- Aaye ataya yii ni nibi ijokoo lẹyin ifọrikanlẹ ikẹyin nibi gbogbo irun, ati lẹyin rakah keji nibi irun olopoo mẹta ati olopoo mẹrin.
- Jijẹ dandan kika At-tahiyyaatu níbi ataya, ati pe o lẹtọọ lati ka eyikeyii ẹgbawa ninu awọn ẹgbawa ataya ninu eyi ti o fi ẹsẹ rinlẹ lati ọdọ Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a-.
- Nini ẹtọ ṣíṣe adura lori irun pẹlu nnkan ti o ba fẹ, lopin igba ti ko ba ti jẹ ẹṣẹ.
- Ṣíṣe bibẹrẹ pẹlu ara ẹni ni nnkan ti a fẹ nibi adura.