- Ọla ti o n bẹ fun àbójútó irun alufajari ati alaasari; nitori pe alufajari maa n waye lasiko igbadun oorun, ti alaasari si maa n waye ni asiko iko-airoju ọmọniyan pẹlu iṣẹ rẹ, ẹni ti o ba n bójú tó mejeeji, o sunmọ ki o rọrun fun un lati bójú tó awọn irun yoku.
- Wọn sọ irun alufajari ati alaasari ni tutu mejeeji; nitori pe irun alufajari otutu oru n bẹ nibẹ, ti otutu ọsan si n bẹ nibi irun alaasari, bi o ti lẹ jẹ pe asiko ti o maa n waye maa n gbóná, ṣùgbọ́n o maa n fuyẹ ju ìgbóná asiko ti o ṣíwájú rẹ lọ, tabi ki sisọ wọn bẹẹ jẹ lábẹ́ fifi ọ̀rọ̀ kan borí ọ̀kan ni, gẹgẹ bi wọn ṣe maa n sọ pe: Al-qomoraan fun oorun ati òṣùpá.