- Ṣisẹnilojukokoro lori ṣiṣọ irun Asr ni akọkọ asiko rẹ ati titete lọ ki i.
- Adehun iya ti o le koko fun ẹni ti o ba gbe irun Asr ju silẹ, ati pe ki èèyàn jẹ ki ó bọ́ ni asiko rẹ tobi ju ki eeyan jẹ ki irun mìíràn bọ́ lọ, oun ni irun aarin ti a ṣa lẹsa ni pato pẹlu aṣẹ ninu ọrọ Rẹ- Ọba ti ọla Rẹ ga-: (Ẹ ṣọ́ àwọn ìrun (wákàtí márààrún) àti (ní pàápàá jùlọ) ìrun ààrin). (Al-Baqarah: 238).