Anabi – ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a – jẹ ẹni ti maa n sọ laarin iforikanlẹ mejeeji pe: «Allāhummọ igfir li, warhamnī, wa ‘āfinī, wahdinī, warzuqnī
Lati ọdọ ọmọ Abbās – ki Ọlọhun yọnu si awọn mejeeji- pé: Anabi – ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a – jẹ ẹni ti maa n sọ laarin iforikanlẹ mejeeji pe: «Allāhummọ igfir li, warhamnī, wa ‘āfinī, wahdinī, warzuqnī».
Abu Daud ati Tirmiziy ati Ibnu Maajah ati Ahmad ni wọ́n gba a wa
Àlàyé
Anabi – ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a – jẹ ẹni ti maa n ṣe adua laarin iforikanlẹ mejeeji nibi irun rẹ pẹlu awọn adua máàrún yii ti Musulumi ni bukaata ti o tobi si i, ti o si tun ko oore ayé àti ti ọjọ ikẹhin sinu, bii wiwa aforijin ati idaabobo awọn ẹṣẹ ati ṣiṣe amojukuro nibẹ, ati pípé ikẹ, ati lila kuro nibi awọn iruju ati awọn adun ati awọn aisan ati idakọlẹ, ati ibeere imọna lọdọ Ọlọhun sibi ododo pẹlu ifẹsẹmulẹ lori rẹ, ati níní ìgbàgbọ́ àti imọ àti iṣẹ oloore, ati níní dukia halaali ti o mọ.
Hadeeth benefits
Ṣiṣe adua yii lofin nibi ijokoo ti o wa laarin iforikanlẹ mejeeji.
Ọla ti n bẹ fun àwọn adua yii latari nkan ti o ko sinu ni oore ayé àti ọjọ ìkẹhìn.
Share
Use the QR code to easily share the message of Islam with others