- Kika adura ìṣírun ni jẹẹjẹ koda ki irun jẹ eyi ti a maa n ki soke.
- Ojúkòkòrò awọn saabe- ki Ọlọhun yọnu si wọn- lori mimọ awọn isẹsi ojiṣẹ - ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- nibi awọn lílọ bibọ rẹ ati iwalojukan rẹ.
- Awọn agbekalẹ miiran wa fun adura iṣirun, ati pe eyi ti o daa julọ ni pe ki ọmọniyan tọ ipasẹ awọn adura iṣirun ti o wa ti o si fi ẹsẹ rinlẹ lati ọdọ rẹ- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a-, ki o si mu eyi wa ni ẹẹkan, ki o mu òmíràn wa nigba mii.