/ “Irẹ Bilal, gbe irun duro, fun wa ni ìsinmi pẹlu rẹ”

“Irẹ Bilal, gbe irun duro, fun wa ni ìsinmi pẹlu rẹ”

Lati ọdọ Saalim ọmọ Abul Jahd, o sọ pe: Arakunrin kan sọ pé: Ìbá ṣe pé mo ti kírun kí n sì sinmi, bí ẹni pé wọ́n dá a lẹ́bi fún ìyẹn, ni o wa sọ pe: Mo gbọ́ ti ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n sọ pe: “Irẹ Bilal, gbe irun duro, fun wa ni ìsinmi pẹlu rẹ”.
Abu Daud ni o gba a wa

Àlàyé

Arakunrin kan ninu awọn saabe sọ pe: Ìbá ṣe pé mo ti kírun ni, kí n sì sinmi, ó dà bíi pé àwọn tó wà láyìíká rẹ̀ dá a lẹ́bi lórí ìyẹn, ni o wa sọ pe: Mo gbọ́ ti Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n sọ pe: Irẹ Bilal! Pe irun, ki o si gbe e dúró; ki a le sinmi pẹlu rẹ; ìyẹn rí bẹ́ẹ̀ fun nnkan ti o n bẹ nibẹ ninu biba Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga- sọrọ ni jẹẹjẹ, ati isinmi fun ẹmi ati ọkan.

Hadeeth benefits

  1. Isinmi ọkan maa n wa pẹlu irun kiki; fun nnkan ti o n bẹ nibẹ ninu biba Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga- sọrọ kẹ́lẹ́kẹ́lẹ́.
  2. Titako ẹni ti o pa ijọsin tì.
  3. Ẹni ti o ba pe nnkan ti o jẹ dandan fun un, ti o si mọ ọrun rẹ kúrò nibẹ, isinmi maa ṣẹlẹ̀ si i pẹlu rẹ ati níní ìmọ̀lára ifayabalẹ.