- Ijẹ dandan fifi ori kan'lẹ pẹlu awọn orikee ara meje ninu irun.
- Kikorira lilọ aṣọ ati irun papọ ni ori irun.
- O jẹ dandan fun ẹni ti n kirun ki o fi ara balẹ ninu irun rẹ, iyẹn ni pe ki o gbe awọn oríkèé iforikanlẹ meje le ilẹ, ki o si fi ara balẹ lori rẹ titi ti yio fi mu iranti ti wọn ṣe lofin nibẹ wa.
- Kikọ kuro nibi lilọ irun jẹ ẹsa fun awọn ọkunrin yatọ si awọn obinrin; nitori pe dajudaju wọn pa obinrin ni aṣẹ pẹlu bibo ara ni ori irun.