/ Ti ẹnikẹni ninu yin ba wọ masalaasi, ki o yaa ki rakaa meji siwaju ki o to jokoo

Ti ẹnikẹni ninu yin ba wọ masalaasi, ki o yaa ki rakaa meji siwaju ki o to jokoo

Lati ọdọ Abu Qataada as-Sulamiyy – ki Ọlọhun yọnu si i – dajudaju ojiṣẹ Ọlọhun – ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a – sọ pe: «Ti ẹnikẹni ninu yin ba wọ masalaasi, ki o yaa ki rakaa meji siwaju ki o to jokoo».
Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí ni

Àlàyé

Anabi – ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - ṣe ẹni ti o ba wa si masalaasi ti o si wọle sibẹ ni eyikeyii asiko, ati fun èyíkéyìí erongba, ni ojukokoro lati ki rakaah meji siwaju ki o to jokoo, ati pe awọn mejeeji ni rakaah meji kiki masalaasi.

Hadeeth benefits

  1. Ninifẹẹ si kiki irun rakaa meji ni ti kiki masalaasi siwaju ijokoo.
  2. Aṣẹ yii wa fun ẹni ti o ba gbero lati jokoo, nitori naa ẹni ti o ba wọ masalaasi ti o si jade siwaju ki o to jokoo, aṣẹ yẹn o ko o sinu.
  3. Ti ẹni ti o fẹ kirun ba wọ masalaasi ti awọn eeyan si n kirun lọwọ, ti o wa darapọ mọ wọn nibẹ, ko bukaata si ki o ki rakaa meji naa mọ.