“Tí ọmọniyan ba nawo lori awọn ara ile rẹ ti o n reti ẹsan rẹ lọdọ Ọlọhun, saara ni o jẹ fun un”
Lati ọdọ Abu Mas’ud- ki Ọlọhun yọnu si i- lati ọdọ Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- o sọ pe: “Tí ọmọniyan ba nawo lori awọn ara ile rẹ ti o n reti ẹsan rẹ lọdọ Ọlọhun, saara ni o jẹ fun un”.
Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí ni
Àlàyé
Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n sọ pe ti ọmọniyan ba nawo lori awọn ara ile rẹ ti inawo wọn jẹ dandan fun un, gẹgẹ bii iyawo rẹ ati awọn obi rẹ mejeeji ati ọmọ rẹ ati awọn ti wọn yatọ si wọn, ti o n fi ìyẹn sunmọ Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga- ti o n reti ẹsan nnkan ti o n na lọdọ Rẹ, dajudaju ẹsan saara n bẹ fun un.
Hadeeth benefits
Gbígba ẹsan ati laada pẹlu ninawo lori awọn ara ile.
Mu’mini maa n wa ojú rere Ọlọhun ati ẹ̀san ti n bẹ lọdọ Rẹ nibi iṣẹ rẹ.
O lẹtọọ lati ni aniyan daadaa nibi gbogbo iṣẹ, ninu ìyẹn ni iṣesi ninawo lori awọn ara ile.
Share
Use the QR code to easily share the message of Islam with others