- Ṣiṣe daadaa nibi ajọṣepọ pẹlu àwọn eniyan, ati dídáríjìn wọ́n, àti ṣiṣamojukuro fún awọn alaini aarin wọn jẹ́ ọ̀kan ninu àwọn okunfa tó ga jù lọ fún lílà ẹru Ọlọhun ní Ọjọ́ Àjíǹde.
- Ṣiṣe daadaa sí awọn eniyan, ṣiṣe mímọ́ nibi ijọsin fun Ọlọ́hun, àti rirankan ikẹ ati àánú Rẹ̀ jẹ́ ọkan ninu àwọn okunfa rírí ìdáríjìn ẹ̀ṣẹ̀.