/ Ti o ba sọ fun ọrẹ rẹ pe: Dakẹ, ni ọjọ jimọ, ti imaamu si n ṣe khutuba lọwọ, o ti sọ ọrọ kọrọ

Ti o ba sọ fun ọrẹ rẹ pe: Dakẹ, ni ọjọ jimọ, ti imaamu si n ṣe khutuba lọwọ, o ti sọ ọrọ kọrọ

Lati ọdọ Abu Hurayra - ki Ọlọhun yọnu si i - dajudaju Ojiṣẹ Ọlọhun - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - sọ pe: «Ti o ba sọ fun ọrẹ rẹ pe: Dakẹ, ni ọjọ jimọ, ti imaamu si n ṣe khutuba lọwọ, o ti sọ ọrọ kọrọ».
Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí ni

Àlàyé

Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - n ṣe alaye wipe dajudaju ninu awọn ẹkọ ti o jẹ dandan fun ẹni ti o ba wa gbọ khutuba jimọ ni: Didakẹ jẹjẹ fun ẹni ti n ṣe khutuba; lati le ba maa ronu si awọn iṣiti yẹn, ati pe dajudaju ẹni ti o ba sọrọ - koda ko jẹ ọrọ diẹ - ti imaamu si n ṣe khutuba lọwọ, ti o wa sọ fun ẹni ti o yatọ si i pe: "Dakẹ" ki o si tun "tẹti", ọla irun jimọ ti bọ fun un.

Hadeeth benefits

  1. Ṣiṣe ọrọ sisọ ni eewọ ni asiko ti a ba n gbọ khutuba, koda ki o jẹ pẹlu kikọ kuro nibi ibajẹ tabi didahun salamọ ati ṣíṣe adua fún ẹni ti o ba sin.
  2. Wọn ṣe ayaafi nibi eleyii ẹni ti o ba n ba imaamu sọrọ tabi ẹni ti imaamu ba n ba sọrọ.
  3. Lilẹtọọ ọrọ sisọ laarin khutuba mejeeji ti a ba bukaata si i.
  4. Ti wọn ba darukọ Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - ti imaamu si n ṣe khutuba lọwọ, dajudaju waa tọrọ ikẹ ati ọla fun un ni jẹ́jẹ́, bakannaa ni ṣiṣe aamiin si adua.