- Dúkìá Ọlọhun ni dúkìá ti o wa ni ọwọ àwọn èèyàn, O fi wọn rólé nibẹ lati maa na an ní ọ̀nà tí ó bá òfin mu, ki wọn si jinna si ṣíṣe e kúmọkùmọ, èyí kárí gbogbo alaṣẹ ati awọn ti wọn yatọ si wọn ninu awọn èèyàn.
- Líle sharia níbi dúkìá gbogbogboo, ati pe ẹni ti o ba jẹ alaṣẹ lori nǹkan kan ninu ẹ, onítọ̀hún maa ṣe ìṣirò bi o ṣe gbà á ati bi o ṣe na an ni Ọjọ́ Àjíǹde.
- Ẹni tí ó n ṣe nnkan ti ko ba ofin mu ninu dúkìá naa maa ko sinu àdéhùn ìyà naa, bóyá o jẹ dúkìá rẹ ni tabi dúkìá ẹlòmíràn.