- Ṣiṣenilojukokoro lori saara ṣíṣe ati ninawo si oju ọna Ọlọhun.
- Ninawo sibi nnkan ti o loore wa ninu awọn okùnfà ìbùkún ti o tobi ju ninu arisiki ati ṣíṣe adipele rẹ, ati ki Ọlọhun fi òmíràn rọ́pò fun ẹrú.
- Hadiisi yii wa nínú ohun ti Anabi, ki ikẹ ati ọla Ọlọhun o maa ba a, gba wa lati ọdọ Oluwa rẹ, ati pe a n pe e ni Hadith Qudsiy tabi Hadith Ilaahiy, oun ni eyi ti gbólóhùn rẹ ati itumọ rẹ wa lati ọdọ Ọlọhun, sibẹsibẹ, ko ni awọn ìròyìn Al-Qur’an ti o ṣe iyatọ rẹ si ohunkohun miiran, gẹgẹ bii ìjọsìn pẹ̀lú kika rẹ, ati ṣíṣe imọra ti a ba fẹ kà á, ati ipenija, ati àìní ikapa lati mu irú rẹ wa, ati bẹẹ bẹẹ lọ.